Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 6:37-54 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Ọmọ Tahati, ọmọ Assiri, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora,

38. Ọmọ Ishari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli.

39. Ati arakunrin rẹ̀ Asafu, ti o duro li ọwọ ọ̀tun rẹ̀, ani Asafu, ọmọ Berakiah, ọmọ Ṣimea,

40. Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah.

41. Ọmọ Etni, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42. Ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,

43. Ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Lefi.

44. Awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Merari duro lọwọ osi: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluku,

45. Ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46. Ọmọ Amsi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣameri.

47. Ọmọ Mahli, ọmọ Muṣi ọmọ Merari, ọmọ Lefi,

48. Arakunrin wọn pẹlu, awọn ọmọ Lefi, li a yàn si oniruru iṣẹ gbogbo ti agọ ile Ọlọrun.

49. Ṣugbọn Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ nrubọ lori pẹpẹ ẹbọ sisun, ati lori pẹpẹ turari, a si yàn wọn si gbogbo iṣẹ ibi mimọ́-jùlọ, ati lati ṣe ètutu fun Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ti pa li aṣẹ.

50. Wọnyi si li awọn ọmọ Aaroni; Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,

51. Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,

52. Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,

53. Sadoku ọmọ rẹ̀, Ahimaasi ọmọ rẹ̀.

54. Wọnyi si ni ibùgbe wọn gẹgẹ bi budo wọn li àgbegbe wọn, ti awọn ọmọ Aaroni, ti idile awọn ọmọ Kohati: nitori ti wọn ni ipin ikini.

Ka pipe ipin 1. Kro 6