Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 6:22-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Awọn ọmọ Kohati; Amminadabu ọmọ rẹ̀, Kora ọmọ rẹ̀, Assiri ọmọ rẹ̀.

23. Elkana ọmọ rẹ̀, ati Ebiasafu ọmọ rẹ̀, ati Assiri ọmọ rẹ̀,

24. Tahati ọmọ rẹ̀, Urieli ọmọ rẹ̀, Ussiah ọmọ rẹ̀, ati Ṣaulu ọmọ rẹ̀,

25. Ati awọn ọmọ Elkana; Amasai, ati Ahimoti.

26. Niti Elkana: awọn ọmọ Elkana; Sofai ọmọ rẹ̀, ati Nahati ọmọ rẹ̀,

27. Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀.

28. Awọn ọmọ Samueli; akọbi Faṣni, ati Abiah.

29. Awọn ọmọ Merari; Mahli, Libni, ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀,

30. Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀, Asaiah ọmọ rẹ̀,

31. Wọnyi si ni awọn ti Dafidi yàn ṣe olori iṣẹ orin ni ile Oluwa, lẹhin igbati apoti-ẹ̀ri Oluwa ti ni isimi.

32. Nwọn si nfi orin ṣe isin niwaju ibugbe agọ ajọ, titi Solomoni fi kọ́ ile Oluwa ni Jerusalemu tan: nwọn si duro ti iṣẹ óye wọn gẹgẹ bi ipa wọn.

33. Wọnyi si li awọn ti o duro pẹlu awọn ọmọ wọn. Ninu awọn ọmọ Kohati: Hemani akọrin, ọmọ Joeli, ọmọ Samueli,

34. Ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,

35. Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

Ka pipe ipin 1. Kro 6