1. NJẸ awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, (nitori on li akọbi; ṣugbọn, bi o ti ṣepe o ba ẹní baba rẹ̀ jẹ, a fi ogun ibi rẹ̀ fun awọn ọmọ Josefu ọmọ Israeli: a kì yio si ka itan-idile na gẹgẹ bi ipò ibi.
2. Nitori Juda bori awọn arakunrin rẹ̀, ati lọdọ rẹ̀ ni alaṣẹ ti jade wá; ṣugbọn ogún ibi jẹ ti Josefu:)
3. Mo ni, awọn ọmọ Rubeni akọbi Israeli ni Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi.
4. Awọn ọmọ Joeli; Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀,
5. Mika ọmọ rẹ̀, Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀,
6. Beera ọmọ rẹ̀, ti Tiglat-pilneseri ọba Assiria kò ni ìgbekun lọ; ijoye awọn ọmọ Rubeni ni iṣe.
7. Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa idile wọn, nigbati a nkà itàn-idile iran wọn, Jeieli, ati Sekariah ni olori.
8. Ati Bela ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli, ti ngbe Aroeri, ani titi de Nebo ati Baalmeoni:
9. Ati niha ariwa, o tẹ̀do lọ titi de ati-wọ̀ aginju lati odò Eufrate; nitoriti ẹran ọ̀sin wọn pọ̀ si i ni ilẹ Gileadi.
10. Ati li ọjọ Saulu, nwọn ba awọn ọmọ Hagari jagun, ẹniti o ṣubu nipa ọwọ wọn: nwọn si ngbe inu agọ wọn ni gbogbo ilẹ ariwa Gileadi.