Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 4:30-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ati ni Betueli, ati ni Horma, ati ni Siklagi,

31. Ati ni Bet-markaboti, ati ni Hasar-susimu, ati ni Bet-birei, ati Ṣaaraimu. Awọn wọnyi ni ilu wọn, titi di ijọba Dafidi.

32. Ileto wọn si ni, Etamu, ati Aini, Rimmoni, ati Tokeni, ati Aṣani, ilu marun:

33. Ati gbogbo ileto wọn, ti o wà yi ilu na ka, de Baali. Wọnyi ni ibugbe wọn, ati itan idile wọn.

34. Ati Meṣobabu ati Jamleki, ati Joṣa ọmọ Amasiah.

35. Ati Joeli, ati Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

36. Ati Elioenai, ati Jaakoba, ati Jeṣohaiah, ati Asaiah, ati Adieli, ati Jesimieli, ati Benaiah,

37. Ati Sisa ọmọ Ṣifi, ọmọ Alloni, ọmọ Jedaiah, ọmọ Ṣimri ọmọ Ṣemaiah;

38. Awọn ti a darukọ wọnyi, ìjoye ni wọn ni idile wọn: ile baba wọn si tan kalẹ gidigidi.

39. Nwọn si wọ̀ oju-ọ̀na Gedori lọ, titi de apa ariwa afonifoji na, lati wá koriko fun agbo ẹran wọn.

40. Nwọn si ri koriko tutù ti o si dara; ilẹ na si gbàye, o si gbe jẹ, o si wà li alafia: nitori awọn ọmọ Hamu li o ti ngbe ibẹ li atijọ.

41. Ati awọn wọnyi ti a kọ orukọ wọn, dé li ọjọ Hesekiah ọba Juda, nwọn si kọlu agọ wọn, ati pẹlu awọn ara Mehuni ti a ri nibẹ, nwọn si bà wọn jẹ patapata titi di oni yi, nwọn si ngbe ipò wọn: nitori koriko mbẹ nibẹ fun agbo ẹran wọn.

42. Omiran ninu wọn, ani ninu awọn ọmọ Simeoni, ẹ̃dẹgbẹta ọkunrin, lọ si òke Seiri, nwọn ni Pelatiah, ati Neariah, ati Refaiah ati Ussieli, awọn ọmọ Iṣi li olori wọn.

43. Nwọn si kọlù iyokù awọn ara Amaleki, ti nwọn salà, nwọn si ngbe ibẹ titi di oni yi.

Ka pipe ipin 1. Kro 4