23. Wọnyi li awọn amọkoko, ati awọn ti ngbe ãrin ọgba ti odi yika; nibẹ ni nwọn ngbe pẹlu ọba fun iṣẹ rẹ̀.
24. Awọn ọmọ Simeoni ni, Nemueli, ati Jamini, Jaribi, Sera, Ṣauli:
25. Ṣallumu ọmọ rẹ̀, Mibsamu ọmọ rẹ̀, Miṣma ọmọ rẹ̀.
26. Ati awọn ọmọ Miṣma; Hammueli ọmọ rẹ̀, Sakkuri ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀.
27. Ṣimei si ni ọmọkunrin mẹrindilogun, ati ọmọbinrin mẹfa; ṣugbọn awọn arakunrin rẹ̀ kò ni ọmọkunrin pupọ, bẹ̃ni kì iṣe idile wọn gbogbo li o rẹ̀ gẹgẹ bi awọn ọmọ Juda.
28. Nwọn si ngbe Beerṣeba, ati Molada, ati Haṣari-ṣuali,
29. Ati ni Bilha, ati ni Esemu, ati ni Toladi,