Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 4:18-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Aya rẹ̀ Jehudijah si bi Jeredi baba Gedori, ati Heberi baba Soke, ati Jekutieli baba Sanoa. Wọnyi si li awọn ọmọ Bitiah ọmọbinrin Farao ti Meredi mu li aya.

19. Ati awọn ọmọ aya Hodiah, arabinrin Nahamu, baba Keila, ara Garmi, ati Eṣtemoa ara Maaka:

20. Awọn ọmọ Ṣimoni si ni Amnoni, ati Rinna, Benhanani, ati Tiloni. Ati awọn ọmọ Iṣi ni, Soheti, ati Bensoheti,

21. Awọn ọmọ Ṣela, ọmọ Juda ni, Eri baba Leka, ati Laada baba Mareṣa ati idile ile awọn ti nwọn nwun aṣọ ọ̀gbọ daradara, ti ile Aṣbea,

22. Ati Jokimu, ati awọn ọkunrin Koseba, ati Joaṣi, ati Sarafu, ti o ni ijọba ni Moabu, ati Jaṣubilehemu. Iwe iranti atijọ ni wọnyi.

23. Wọnyi li awọn amọkoko, ati awọn ti ngbe ãrin ọgba ti odi yika; nibẹ ni nwọn ngbe pẹlu ọba fun iṣẹ rẹ̀.

24. Awọn ọmọ Simeoni ni, Nemueli, ati Jamini, Jaribi, Sera, Ṣauli:

25. Ṣallumu ọmọ rẹ̀, Mibsamu ọmọ rẹ̀, Miṣma ọmọ rẹ̀.

26. Ati awọn ọmọ Miṣma; Hammueli ọmọ rẹ̀, Sakkuri ọmọ rẹ̀, Ṣimei ọmọ rẹ̀.

27. Ṣimei si ni ọmọkunrin mẹrindilogun, ati ọmọbinrin mẹfa; ṣugbọn awọn arakunrin rẹ̀ kò ni ọmọkunrin pupọ, bẹ̃ni kì iṣe idile wọn gbogbo li o rẹ̀ gẹgẹ bi awọn ọmọ Juda.

28. Nwọn si ngbe Beerṣeba, ati Molada, ati Haṣari-ṣuali,

Ka pipe ipin 1. Kro 4