Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 3:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI li awọn ọmọ Dafidi, ti a bi fun u ni Hebroni; akọbi Amnoni, lati ọdọ Ahinoamu ara Jesreeli; ekeji Danieli, lati ọdọ Abigaili ara Karmeli;

2. Ẹkẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Gesuri; ẹkẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti.

3. Ẹkarun, Ṣefatiah lati ọdọ Abitali; ẹkẹfa Itreamu lati ọdọ Ẹgla aya rẹ̀.

4. Awọn mẹfa wọnyi li a bi fun u ni Hebroni; nibẹ li o si jọba li ọdun meje on oṣù mẹfa: ati ni Jerusalemu li o jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.

5. Wọnyi li a si bi fun u ni Jerusalemu; Ṣimea, ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni, mẹrin, lati ọdọ Batṣua ọmọbinrin Ammieli:

6. Abhari pẹlu, ati Eliṣama, ati Elifeleti,

7. Ati Noga, ati Nefegi, ati Jafia,

Ka pipe ipin 1. Kro 3