Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 28:17-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ati wura didara fun pàlaka mimu ẹran, ati ọpọn, ati ago: ati fun awo-koto wura nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto; ati nipa ìwọn fun olukuluku awo-koto fadakà:

18. Ati fun pẹpẹ turari, wura daradara nipa ìwọn; ati apẹrẹ iduro awọn kerubu ti wura, ti nwọn nà iyẹ wọn, ti nwọn si bo apoti ẹri majẹmu Oluwa mọlẹ

19. Gbogbo eyi wà ninu iwe lati ọwọ Oluwa ẹniti o kọ́ mi niti gbogbo iṣẹ apẹrẹ wọnyi.

20. Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa.

21. Si kiyesi i, ipin awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, wà pẹlu rẹ fun oniruru ìsin ile Ọlọrun: iwọ ni pẹlu rẹ oniruru enia, ọlọkàn fifẹ, ẹniti o ni oye gbogbo iṣẹ fun oniruru iṣẹ: pẹlupẹlu awọn ijoye ati gbogbo awọn enia wà pẹlu rẹ fun gbogbo ọ̀ran rẹ.

Ka pipe ipin 1. Kro 28