Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 26:8-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Gbogbo wọnyi ti inu awọn ọmọ Obed-Edomu, ni: awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn arakunrin wọn, akọni enia ati alagbara fun ìsin na, jẹ mejilelọgọta lati ọdọ Obed-Edomu;

9. Meṣelemiah si ni awọn ọmọ ati arakunrin, alagbara enia, mejidilogun.

10. Hosa pẹlu, ninu awọn ọmọ Merari, ni ọmọ; Simri olori (nitori bi on kì iti iṣe akọbi ṣugbọn baba rẹ̀ fi jẹ olori),

11. Hilkiah ekeji, Tebaliah ẹkẹta, Sekariah ẹkẹrin: gbogbo awọn ọmọ ati awọn arakunrin Hosa jẹ mẹtala.

12. Ninu awọn wọnyi ni ipin awọn adena, ani ninu awọn olori ọkunrin, ti nwọn ni iṣẹ gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn, lati ṣe iranṣẹ ni ile Oluwa.

13. Nwọn si ṣẹ keké, bi ti ẹni-kekere bẹ̃ni ti ẹni-nla, gẹgẹ bi ile baba wọn, fun olukuluku ẹnu-ọ̀na.

14. Iṣẹ keké iha ila-õrun bọ̀ sọdọ Ṣelemiah. Nigbana ni nwọn ṣẹ keké fun Sekariah ọmọ rẹ̀, ọlọgbọ́n igbimọ; iṣẹ keké rẹ̀ si bọ si iha ariwa.

15. Sọdọ Obed-Edomu niha gusù; ati sọdọ awọn ọmọ rẹ̀ niha ile Asuppimu (yara iṣura).

16. Ti Suppimu ati Hosa niha iwọ-õrun li ẹnu-ọ̀na Ṣalleketi, nibi ọ̀na igòke lọ, iṣọ kọju si iṣọ.

17. Niha ìla-õrùn awọn ọmọ Lefi mẹfa (nṣọ), niha ariwa mẹrin li ojojumọ, niha gusù mẹrin li ojojumọ, ati ninu Asuppimu (ile iṣura) mejimeji.

18. Ni ibasa niha iwọ-õrùn, mẹrin li ọ̀na igòke-lọ ati meji ni ibasa.

19. Wọnyi ni ipin awọn adena lati inu awọn ọmọ Kore, ati lati inu awọn ọmọ Merari.

20. Lati inu awọn ọmọ Lefi, Ahijah li o wà lori iṣura ile Ọlọrun, ati lori iṣura nkan wọnni ti a yà si mimọ́.

21. Awọn ọmọ Laadani; awọn ọmọ Laadani ara Gerṣoni, awọn olori baba, ani ti Laadani ara Gerṣoni ni Jehieli.

22. Awọn ọmọ Jehieli; Setamu, ati Joeli arakunrin rẹ̀, ti o wà lori iṣura ile Oluwa.

Ka pipe ipin 1. Kro 26