Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 26:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITI ipin awọn adena: niti awọn ọmọ Kosa ni Meṣelemiah ọmọ Kore, ninu awọn ọmọ Asafu.

2. Ati awọn ọmọ Meṣelemiah ni Sekariah akọbi, Jediaeli ekeji, Sebadiah ẹkẹta, Jatnieli ẹkẹrin,

3. Elamu ẹkarun, Johanani ẹkẹfa, Elioenai ekeje.

4. Awọn ọmọ Obed-Edomu si ni Ṣemaiah akọbi, Jehosabadi ekeji, Joa ẹkẹta, ati Sakari ẹkẹrin, ati Netaneeli ẹkarun,

5. Ammieli ẹkẹfa, Issakari ekeje, Peulltai ẹkẹjọ: Ọlọrun sa bukún u.

6. Ati fun Ṣemaiah ọmọ rẹ̀ li a bi awọn ọmọ ti nṣe olori ni ile baba wọn: nitori alagbara akọni enia ni nwọn.

7. Awọn ọmọ Ṣemaiah; Otni, ati Refaeli, ati Obedi, Elsabadi, arakunrin ẹniti iṣe alagbara enia, Elihu, ati Semakiah.

8. Gbogbo wọnyi ti inu awọn ọmọ Obed-Edomu, ni: awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn arakunrin wọn, akọni enia ati alagbara fun ìsin na, jẹ mejilelọgọta lati ọdọ Obed-Edomu;

9. Meṣelemiah si ni awọn ọmọ ati arakunrin, alagbara enia, mejidilogun.

Ka pipe ipin 1. Kro 26