Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 24:16-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ẹkọkandilogun fun Petahiah, ogun fun Jehesekeli,

17. Ẹkọkanlelogun fun Jakini, ekejilelogun fun Gamuli,

18. Ẹkẹtalelogun fun Delaiah, ẹkẹrinlelogun fun Maasiah.

19. Wọnyi ni itò wọn ni ìsin wọn lati lọ sinu ile Oluwa, gẹgẹ bi iṣe wọn nipa ọwọ Aaroni baba wọn, bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti paṣẹ fun u.

20. Iyokù awọn ọmọ Lefi ni wọnyi: Ninu awọn ọmọ Amramu; Ṣubaeli: ninu awọn ọmọ Ṣubaeli; Jehediah.

21. Nipa ti Rehabiah; ninu awọn ọmọ Rehabiah, ekini Iṣṣiah.

22. Ninu awọn Ishari; Ṣelomoti; ninu awọn ọmọ Ṣelomoti; Jahati.

23. Awọn ọmọ Hebroni: Jeriah ikini; Amariah ekeji, Jahasieli ẹkẹta, Jekamamu ẹkẹrin.

24. Awọn ọmọ Ussieli; Mika: awọn ọmọ Mika; Ṣamiri.

25. Arakunrin Mika ni Iṣṣiah; ninu awọn ọmọ Iṣṣiah; Sekariah.

26. Awọn ọmọ Merari ni Mali ati Muṣi: awọn ọmọ Jaasiah; Beno;

27. Awọn ọmọ Merari nipa Jaasiah; Beno ati Ṣohamu, ati Sakkuri, ati Ibri.

28. Lati ọdọ Mali ni Eleasari ti wá, ẹniti kò li ọmọkunrin.

Ka pipe ipin 1. Kro 24