Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 20:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si ṣe lẹhin eyi li ogun si de ni Geseri pẹlu awọn ara Filistia; li akokò na ni Sibbekai ara Huṣa pa Sippai, ti inu awọn ọmọ òmiran: a si tẹ ori wọn ba.

5. Ogun si tun wà pẹlu awọn ara Filistia; Elhanani ọmọ Jairi si pa Lahamu arakunrin Goliati ara Gati, igi ọ̀kọ rẹ̀ si dabi ìti awunṣọ.

6. Ogun si tun wà ni Gati, nibiti ọkunrin gigun kan gbe wà, ika ati ọmọ-ẹsẹ ẹniti o jẹ mẹrinlelogun, mẹfa li ọwọ kọkan, ati mẹfa li ẹṣẹ kọkan, a si bi i pẹlu fun òmiran.

7. Ṣugbọn nigbati o pe Israeli ni ija, Jonatani ọmọ Ṣimea arakunrin Dafidi pa a.

8. Awọn wọnyi li a bi fun òmiran ni Gati; nwọn si tipa ọwọ Dafidi ṣubu, ati ipa ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Kro 20