Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 2:45-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

45. Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri.

46. Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi.

47. Ati awọn ọmọ Jahdai; Regemu, ati Jotamu, ati Geṣamu, ati Peleti, ati Efa, ati Ṣaafu.

48. Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana.

49. On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa.

50. Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu,

51. Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi.

52. Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti.

53. Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá.

54. Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori.

55. Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

Ka pipe ipin 1. Kro 2