3. Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela; awọn mẹta yi ni Batṣua, ara Kenaani, bi fun u. Eri, akọbi Juda, si buru loju Oluwa; on si pa a.
4. Tamari aya-ọmọ rẹ̀ si bi Faresi ati Sera fun u. Gbogbo awọn ọmọ Juda jẹ marun.
5. Awọn ọmọ Faresi; Hesroni; ati Hamuli.
6. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.
7. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.
8. Awọn ọmọ Etani; Asariah.
9. Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai.
10. Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;
11. Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi.
12. Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse,
13. Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta.