Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 2:27-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri.

28. Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri.

29. Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u.

30. Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.

31. Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.

32. Ati awọn ọmọ Jada arakunrin Ṣammai; Jeteri, ati Jonatani; Jeteri si kú laini ọmọ.

33. Awọn ọmọ Jonatani; Peleti, ati Sasa. Wọnyi ni awọn ọmọ Jerahmeeli.

34. Ṣeṣani kò si ni ọmọkunrin, bikọṣe ọmọbinrin. Ṣeṣani si ni iranṣẹ kan, ara Egipti, orukọ, ẹniti ijẹ Jarha.

35. Ṣeṣani si fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Jarha iranṣẹ rẹ̀ li aya; on si bi Attai fun u.

36. Attai si bi Natani, Natani si bi Sabadi,

37. Sabadi si bi Eflali, Eflali si bi Obedi,

38. Obedi si bi Jehu, Jehu si bi Asariah,

39. Asariah si bi Helesi, Helesi si bi Elasa,

40. Elasa si bi Sisamai, Sisamai si bi Ṣallumu,

41. Ṣallumu si bi Jekamiah, Jekamiah si bi Eliṣama.

42. Awọn ọmọ Kalebu arakunrin Jerahmeeli si ni Meṣa akọbi rẹ̀, ti iṣe baba Sifi; ati awọn ọmọ Mareṣa baba Hebroni.

43. Awọn ọmọ Hebroni; Kora, ati Tappua, ati Rekemu, ati Ṣema.

44. Ṣema si bi Rahamu, baba Jorkeamu: Rekemu si bi Ṣammai.

45. Ati ọmọ Ṣammai ni Maoni: Maoni si ni baba Bet-suri.

46. Efa obinrin Kalebu si bi Harani, ati Mosa, ati Gasesi: Harani si bi Gasesi.

Ka pipe ipin 1. Kro 2