Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 2:21-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Lẹhin na Hesroni si wọle tọ̀ ọmọ Makiri obinrin baba Gileadi, on gbe e ni iyawo nigbati o di ẹni ọgọta ọdun, on si bi Segubu fun u.

22. Segubu si bi Jairi, ti o ni ilu mẹtalelogun ni ilẹ Gileadi.

23. Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.

24. Ati lẹhin igbati Hesroni kú ni ilu Kaleb-Efrata, ni Abiah aya Hesroni bi Aṣuri baba Tekoa fun u.

25. Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah.

26. Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu.

27. Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri.

Ka pipe ipin 1. Kro 2