Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 19:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nigbati Joabu ri pe a doju ija kọ on, niwaju ati lẹhin, o yàn ninu gbogbo ãyo Israeli, o si tẹ ogun wọn si awọn ara Siria.

11. O si fi iyokù awọn enia le Abiṣai arakunrin rẹ̀ lọwọ, nwọn si tẹ ogun si awọn ọmọ Ammoni.

12. On si wipe, Bi awọn ara Siria ba le jù fun mi, nigbana ni iwọ o ran mi lọwọ: ṣugbọn bi awọn ọmọ Ammoni ba le jù fun ọ, nigbana li emi o ràn ọ lọwọ.

13. Ṣe giri ki o si jẹ ki a huwa akọni fun enia wa ati fun ilu Ọlọrun wa: ki Oluwa ki o si ṣe eyi ti o dara loju rẹ̀.

14. Bẹ̃ni Joabu ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀ sún siwaju awọn ara Siria si ibi ija: nwọn si sá niwaju rẹ̀.

15. Nigbati awọn ọmọ Ammoni si ri pe awọn ara Siria sá, awọn pẹlu sá niwaju Abiṣai arakunrin rẹ̀, nwọn si wọ̀ ilu lọ. Nigbana ni Joabu wá si Jerusalemu.

16. Nigbati awọn ara Siria ri pe a le wọn niwaju Israeli, nwọn ran onṣẹ, nwọn si fà awọn ara Siria ti mbẹ lòke odò: Ṣofaki olori ogun Hadareseri sì ṣiwaju wọn.

17. A si sọ fun Dafidi; on si ko gbogbo Israeli jọ, o si gòke odò Jordani o si yọ si wọn, o si tẹ ogun si wọn. Bẹ̃ni nigbati Dafidi tẹ ogun si awọn ara Siria, nwọn ba a jà.

18. Ṣugbọn awọn ara Siria sá niwaju Israeli, Dafidi si pa ẹ̃dẹgbarin enia ninu awọn ara Siria ti o wà ninu kẹkẹ́, ati ọkẹ-meji ẹlẹsẹ, o si pa Ṣofaki olori ogun na.

Ka pipe ipin 1. Kro 19