Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 18:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.

7. Dafidi si gbà awọn asa wura ti mbẹ lara awọn iranṣẹ Hadareseri, o si mu wọn wá si Jerusalemu.

8. Lati Tibhati pẹlu ati lati Kuni, ilu Hadareseri ni Dafidi ko ọ̀pọlọpọ idẹ, eyiti Solomoni fi ṣe okun idẹ, ọwọn wọnni, ati ohun elo idẹ wọnni.

9. Nigbati Tou ọba Hamati gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadareseri ọba Soba.

10. O ran Hadoramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba lati ki i ati lati yọ̀ fun u, nitoriti o ti ba Hadareseri jà o si ti ṣẹgun rẹ̀; (nitori Tou ti jẹ ọta Hadareseri) o si ni oniruru ohun elo wura ati ti fadakà ati idẹ pẹ̀lu rẹ̀.

11. Awọn pẹlu ni Dafidi yà si mimọ́ fun Oluwa pẹlu fadakà ati wura ti o ko lati ọdọ gbogbo orilẹ-ède wọnni wá; lati Edomu, ati lati Moabu, ati lati ọdọ awọn ọmọ Ammoni, ati lati ọdọ awọn ara Filistia, ati lati Amaleki wá,

Ka pipe ipin 1. Kro 18