Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 18:13-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O si fi ẹgbẹ-ogun si Edomu: ati gbogbo awọn ara Edomu si di iranṣẹ Dafidi. Bayi li Oluwa ngbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.

14. Bẹ̃ ni Dafidi jọba lori gbogbo Israeli, o si ṣe idajọ ati otitọ larin awọn enia rẹ̀.

15. Joabu ọmọ Seruiah si wà lori ogun; ati Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọwe-iranti.

16. Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Abimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; ati Ṣafṣa ni akọwe;

17. Benaiah ọmọ Jehoiada li o si wà lori awọn Kereti ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si li olori lọdọ ọba.

Ka pipe ipin 1. Kro 18