Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 18:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi kọlu awọn ara Filistia, o si ṣẹ́ wọn, o si gbà Gati ati ilu rẹ̀ lọwọ awọn ara Filistia.

2. O si kọlu Moabu, awọn ara Moabu si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá.

3. Dafidi si kọlu Hadareseri ọba Soba ni Hamati bi o ti nlọ lati fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ leti odò Euferate.

4. Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ́, ati ẹ̃dẹgbarun ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa ẹlẹsẹ lọwọ rẹ̀: Dafidi si ja iṣan ẹsẹ gbogbo awọn ẹṣin kẹkẹ́ na, ṣugbọn o pa ọgọrun ẹṣin kẹkẹ́ mọ ninu wọn.

5. Nigbati awọn ara Siria ti Damasku wá lati ran Hadareseri ọba Soba lọwọ, Dafidi pa ẹgbã mọkanla enia ninu awọn ara Siria.

6. Dafidi si fi ẹgbẹ-ogun si Siria ti Damasku; awọn ara Siria si di iranṣẹ Dafidi, nwọn si mu ọrẹ wá. Bayi li Oluwa gbà Dafidi nibikibi ti o ba nlọ.

Ka pipe ipin 1. Kro 18