Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 17:24-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.

25. Nitori iwọ, Ọlọrun mi, ti ṣi iranṣẹ rẹ li eti pe, Iwọ o kọ́ ile kan fun u: nitorina ni iranṣẹ rẹ ri i lati gbadua niwaju rẹ.

26. Njẹ nisisiyi Oluwa, Iwọ li Ọlọrun, iwọ si ti sọ ọ̀rọ ore yi fun iranṣẹ rẹ;

27. Njẹ nisisiyi jẹ ki o wù ọ lati bukún ile iranṣẹ rẹ, ki o le ma wà niwaju rẹ lailai: nitori iwọ Oluwa, ẹniti o sure fun, ire ni o si ma jẹ lailai.

Ka pipe ipin 1. Kro 17