Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 17:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Emi o jẹ baba fun u, on o si jẹ ọmọ fun mi; emi kì yio si gbà ãnu mi kuro lọdọ rẹ̀, bi mo ti gbà a lọwọ ẹniti o ti wà ṣaju rẹ:

14. Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.

15. Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.

16. Dafidi ọba si wá, o si joko niwaju Oluwa, o si wipe, Tali emi Oluwa Ọlọrun, ati kini ile mi, ti iwọ si mu mi de ihinyi?

17. Ohun kekere si li eyi li oju rẹ, Ọlọrun: iwọ si ti sọ pẹlu sipa ile iranṣẹ rẹ fun akokò jijin ti mbọ, o si ka mi si bi iṣe enia giga, Oluwa Ọlọrun.

18. Kini Dafidi le tun ma sọ pẹlu fun ọ niti ọlá ti a bù fun iranṣẹ rẹ? iwọ sa mọ̀ iranṣẹ rẹ.

19. Oluwa, nitoriti iranṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi ti inu rẹ, ni iwọ ti ṣe gbogbo ohun nlanla yi, ni sisọ gbogbo nkan nla wọnyi di mimọ̀.

Ka pipe ipin 1. Kro 17