Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 16:32-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Jẹ ki okun ki o ma ho, ati ẹkún rẹ̀: jẹ ki papa-oko tùtu ki o yọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀.

33. Nigbana ni awọn igi igbo yio ma ho niwaju Oluwa, nitori ti o mbọ wá ṣe idajọ aiye.

34. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.

35. Ki ẹ si wipe, Gbà wa Ọlọrun igbala wa, si gbá wa jọ, ki o si gbà wa lọwọ awọn keferi, ki awa ki o le ma fi ọpẹ fun orukọ rẹ mimọ́, ki a si le ma ṣogo ninu iyin rẹ.

36. Olubukún li Oluwa Ọlọrun Israeli lai ati lailai. Gbogbo awọn enia si wipe, Amin, nwọn si yìn Oluwa.

37. Bẹ̃ li o fi Asafu ati awọn arakunrin rẹ̀ silẹ nibẹ niwaju apoti ẹri majẹmu Oluwa lati ma jọsìn niwaju apoti ẹri na nigbagbogbo, bi iṣẹ ojojumọ ti nfẹ.

38. Ati Obed-Edomu pẹlu awọn arakunrin wọn, enia mejidilãdọrin; ati Obed-Edomu ọmọ Jedutuni, ati Hosa lati ma ṣe adena:

39. Sadoku alufa, ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn alufa, niwaju agọ Oluwa, ni ibi giga ti o wà ni Gibeoni,

40. Lati ma ru ẹbọ sisun si Oluwa lori pẹpẹ ẹbọ sisun nigbagbogbo li owurọ ati li alẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti a kọ ninu ofin Oluwa, ti o pa li aṣẹ fun Israeli;

41. Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni, ati awọn iyokù ti a yàn, ti a si pe li orukọ, lati ma fi ìyin fun Oluwa, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;

42. Ati pẹlu wọn Hemani ati Jedutuni pẹlu ipè ati kimbali fun awọn ti yio ma pariwo, ati pẹlu ohun èlo orin Ọlọrun. Awọn ọmọ Jedutuni li awọn adena.

43. Gbogbo awọn enia si lọ olukuluku si ile rẹ̀: Dafidi yipada lati sure fun ile rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Kro 16