Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 15:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bẹ̃ li awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ya ara wọn si mimọ́ lati gbe apoti ẹri Oluwa Ọlọrun Israeli gòke wá.

15. Awọn ọmọ Lefi si rù apoti ẹri Ọlọrun bi Mose ti pa a li aṣẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, nwọn fi ọpa rù u li ejika wọn.

16. Dafidi si wi fun olori awọn ọmọ Lefi pe ki nwọn yàn awọn arakunrin wọn, awọn akọrin pẹlu ohun èlo orin, psalteri ati duru, ati kimbali; ti ndún kikan ti o si nfi ayọ gbé ohùn soke.

17. Bẹ̃ li awọn ọmọ Lefi yan Hemani ọmọ Joeli; ati ninu awọn arakunrin rẹ̀, Asafu ọmọ Berekiah; ati ninu awọn ọmọ Merari arakunrin wọn, Etani ọmọ Kuṣaiah;

18. Ati pẹlu wọn awọn arakunrin wọn li ọwọ́ keji; Sekariah, Beni, ati Jaasieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Unni, Eliabu, ati Benaiah, ati Maaseiah, ati Obed-Edomu, ati Jeieli awọn adena.

19. Awọn akọrin si ni Hemani, Asafu, ati Etani, ti awọn ti kimbali ti ndun kikan;

Ka pipe ipin 1. Kro 15