Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 15:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI si kọ́ ile fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, o si pese ipò kan fun apoti ẹri Ọlọrun, o si pa agọ kan fun u.

2. Nigbana ni Dafidi wipe, Ẹnikan kò yẹ lati rù apoti ẹri Ọlọrun bikoṣe awọn ọmọ Lefi; nitori awọn ni Oluwa ti yàn lati ma gbé apoti ẹri Ọlọrun, ati lati ma ṣe iranṣẹ fun u titi lai.

3. Dafidi si ko gbogbo Israeli jọ si Jerusalemu, lati gbé apoti ẹri Oluwa gòke lọ si ipò rẹ̀ ti o ti pese fun u.

4. Dafidi si pè awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi jọ.

5. Ninu awọn ọmọ Kohati; Urieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọfa:

6. Ninu awọn ọmọ Merari; Asaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba o le ogun:

7. Ninu awọn ọmọ Gerṣomu; Joeli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ãdoje:

8. Ninu awọn ọmọ Elisafani; Ṣemaiah olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ igba.

9. Ninu awọn ọmọ Hebroni; Elieli olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ ọgọrin:

10. Ninu awọn ọmọ Ussieli; Aminadabu olori, ati awọn arakunrin rẹ̀ mejilelãdọfa.

11. Dafidi si ranṣẹ pè Sadoku ati Abiatari awọn alufa; ati awọn ọmọ Lefi, Urieli, Asaiah, ati Joeli, Ṣemaiah, ati Elieli, ati Aminadabu;

Ka pipe ipin 1. Kro 15