Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 12:27-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Jehoiada olori fun Aaroni, ẹgbẹ̃dogun enia o le ẽdẹgbẹrin si wà pẹlu rẹ̀.

28. Ati Sadoku, akọni ọdọmọkunrin, ati ninu ile baba rẹ̀ olori mejilelogun.

29. Ati ninu awọn ọmọ Benjamini, awọn arakunrin Saulu ẹgbẹ̃dogun: nitori titi di isisiyi, ọ̀pọlọpọ ninu wọn li o ti ntọju iṣọ ile Saulu.

30. Ati ninu awọn ọmọ Efraimu ẹgbãwa o le ẹgbẹrin, akọni ọkunrin, enia olorukọ ni nwọn ni ile baba wọn.

31. Ati àbọ ẹ̀ya Manasse ẹgbãsan, ti a yan nipa orukọ, lati lọ fi Dafidi jẹ ọba.

32. Ati ninu awọn ọmọ Issakari, ti o ni oye akoko, lati mọ̀ ohun ti Israeli iba ma ṣe; olori wọn jẹ igba; ati gbogbo awọn arakunrin wọn mbẹ ni ikawọ wọn.

33. Ninu ti Sebuluni, iru awọn ti o jade lọ si ogun ti o mọ̀ ogun iwé, pẹlu gbogbo ohun èlo ogun, ẹgbamẹ̃dọgbọn; ti nwọn kì ifi iye-meji tẹgun.

34. Ati ninu ti Naftali ẹgbẹrun olori ogun, ati pẹlu wọn ti awọn ti asa ati ọ̀kọ ẹgbã mejidilogun o le ẹgbẹrun.

35. Ati ninu awọn ọmọ Dani ti o mọ̀ ogun iwé, ẹgbã mẹtala o le ẹgbẹta.

36. Ati ninu ti Aṣeri, iru awọn ti njade lọ si ogun, ti o mọ̀ ogun iwé, ọkẹ meje.

37. Ati li apa keji odò Jordani, ninu ti awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati abọ ẹya Manasse, pẹlu gbogbo onirũru ohun elo ogun fun ogun ọ̀kọ, ọkẹ mẹfa.

38. Gbogbo awọn ọkunrin ogun wọnyi ti nwọn mọ̀ bi a iti itẹ ogun, nwọn fi ọkàn pipe wá si Hebroni, lati fi Dafidi jọba lori Israeli: gbogbo awọn iyokù ninu Israeli si jẹ oninu kan pẹlu lati fi Dafidi jẹ ọba.

39. Nibẹ, ni nwọn si wà pẹlu Dafidi ni ijọ mẹta, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nitoriti awọn ará wọn ti pèse fun wọn.

40. Pẹlupẹlu awọn ti o sunmọ wọn, ani titi de ọdọ Issakari, ati Sebuluni, ati Naftali, mu akara wá lori kẹtẹkẹtẹ, ati lori ibakasiẹ, ati lori ibãka, ati lori malu, ani onjẹ ti iyẹfun, eso ọ̀pọtọ, ati eso àjara gbigbẹ, ati ọti-waini, ati ororo, ati malu, ati agutan li ọ̀pọlọpọ: nitori ti ayọ̀ wà ni Israeli.

Ka pipe ipin 1. Kro 12