Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 12:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI si li awọn ti o tọ̀ Dafidi wá si Siklagi, nigbati o fi ara rẹ̀ pamọ, nitori Saulu ọmọ Kiṣi: awọn wọnyi si wà ninu awọn akọni ti nṣe oluranlọwọ ogun na.

2. Nwọn le tafa, nwọn si le fi ọwọ ọtún ati ọwọ ọ̀si sọ okuta, ati fi ọrun tafa, ani ninu awọn arakunrin Saulu ti Benjamini.

3. Ahieseri ni olori, ati Joaṣi, awọn ọmọ Ṣemaa ara Gibea; ati Jesieli ati Peleti, awọn ọmọ Asmafeti; ati Beraka, ati Jehu ara Anatoti,

4. Ati Ismaiah ara Gibeoni, akọni ninu awọn ọgbọ̀n, ati lori ọgbọ̀n (enia) ati Jeremiah, ati Jahasieli, ati Johanani, ati Josabadi ara Gedera.

5. Elusai ati Jeremoti, ati Bealiah, ati Ṣemariah, ati Ṣefatiah ara Harofi,

6. Elkana, ati Jesiah, ati Asareelti ati Joeseri, ati Jaṣobeamu, awọn ara Kora,

7. Ati Joela, ati Sebadiah, awọn ọmọ Jerohamu ti Gedori.

8. Ati ninu awọn ara Gadi, awọn ọkunrin akọni kan ya ara wọn sọdọ Dafidi ninu iho ni iju, awọn ọkunrin ogun ti o yẹ fun ija ti o le di asà on ọ̀kọ mu, oju awọn ẹniti o dabi oju kiniun, nwọn si yara bi agbọnrin lori awọn òke nla;

9. Eseri ekini, Obadiah ekeji, Eliobu ẹkẹta,

10. Miṣmanna ẹkẹrin, Jeremiah ẹkarun,

11. Attai ẹkẹfa, Elieli ekeje,

12. Johanani ẹkẹjọ, Elsabadi ẹkẹsan,

13. Jeremiah ẹkẹwa, Makbanai ẹkọkanla.

14. Awọn wọnyi li awọn ọmọ Gadi, awọn olori ogun: ẹniti o kere jù to fun ọgọrun enia, ati ẹniti o pọ̀ju to fun ẹgbẹrun.

Ka pipe ipin 1. Kro 12