Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 1:37-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

37. Awọn ọmọ Reueli: Nahati, Sera, Ṣamma, ati Missa.

38. Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Diṣoni, ati Esari, ati Diṣani.

39. Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si ni arabinrin Lotani.

40. Awọn ọmọ Ṣobali; Aliani, ati Manahati, ati Ebali, Ṣefi, ati Onamu. Ati awọn ọmọ Sibeoni; Aiah, ati Ana.

41. Awọn ọmọ Ana; Diṣoni. Ati awọn ọmọ Diṣoni; Amrani, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani.

42. Awọn ọmọ Eseri; Bilhani, ati Safani, ati Jakani. Awọn ọmọ Diṣani; Usi, ati Arani.

43. Wọnyi si ni awọn ọba ti o jẹ ni ilẹ Edomu, ki ọba kan to jẹ lori awọn ọmọ Israeli: Bela ọmọ Beori: orukọ ilu rẹ̀ si ni Dinhaba.

44. Nigbati Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀.

45. Nigbati Jobabu kú, Huṣamu ti ilẹ awọn ara Temani si jọba ni ipò rẹ̀.

46. Nigbati Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ti o kọlu Midiani ni ìgbẹ Moabu, jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Afiti.

47. Nigbati Hadadi kú, Samla ti Masreka jọba ni ipò rẹ̀.

48. Nigbati Samla kú, Ṣaulu ti Rehoboti leti odò jọba ni ipò rẹ̀.

49. Nigbati Ṣaulu kú, Baal-hanani, ọmọ Akbori, jọba ni ipò rẹ̀.

50. Nigbati Baal-hanani kú, Hadadi si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ ni Pai; orukọ aya rẹ̀ si ni Mehetabeeli, ọmọbinrin Matredi, ọmọbinrin Mesahabu.

51. Hadadi si kú. Awọn bãlẹ Edomu ni; Timna bãlẹ, Aliah bãlẹ, Jeteti bãlẹ.

52. Aholibama bãlẹ, Ela bãlẹ, Pinoni bãlẹ,

53. Kenasi bãlẹ, Temani bãlẹ, Mibsari bãlẹ,

Ka pipe ipin 1. Kro 1