Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 7:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O kọ́ ile-igbó Lebanoni pẹlu; gigùn rẹ̀ jasi ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ adọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ ọgbọ̀n igbọnwọ, lori ọ̀wọ́ mẹrin opó igi kedari, ati idabu igi kedari lori awọn opó na.

3. A si fi igi kedari tẹ́ ẹ loke lori iyara ti o joko lori ọwọ̀n marunlelogoji, mẹdogun ni ọ̀wọ́.

4. Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.

5. Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.

6. O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 7