Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 7:13-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Solomoni ọba si ranṣẹ, o si mu Hiramu lati Tire wá.

14. Ọmọkunrin opó kan ni, lati inu ẹya Naftali, baba rẹ̀ si ṣe ara Tire, alagbẹdẹ idẹ: on si kún fun ọgbọ́n, ati oye, ati ìmọ lati ṣe iṣẹkiṣẹ ni idẹ. O si tọ̀ Solomoni ọba wá, o si ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀.

15. O si dà ọwọ̀n idẹ meji, igbọnwọ mejidilogun ni giga ọkọkan: okùn igbọnwọ mejila li o si yi ọkọkan wọn ka.

16. O si ṣe ipari meji ti idẹ didà lati fi soke awọn ọwọ̀n na: giga ipari kan jẹ igbọnwọ marun, ati giga ipari keji jẹ igbọnwọ marun:

17. Ati oniruru iṣẹ, ati ohun wiwun iṣẹ ẹ̀wọn fun awọn ipari ti mbẹ lori awọn ọwọ̀n na; meje fun ipari kan, ati meje fun ipari keji.

18. O si ṣe awọn pomegranate ani ọ̀wọ́ meji yikakiri lara iṣẹ àwọn na, lati fi bò awọn ipari ti mbẹ loke: bẹ̃li o si ṣe fun ipari keji.

19. Ati ipari ti mbẹ li oke awọn ọwọ̀n ti mbẹ ni ọ̀dẹdẹ na ti iṣẹ lili, ni igbọnwọ mẹrin.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 7