Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 6:6-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na.

7. Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.

8. Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta.

9. Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na.

10. O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na.

11. Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe,

12. Nipa ti ile yi ti iwọ nkọ́ lọwọ nì, bi iwọ o ba rin ninu aṣẹ mi, ti iwọ o si ṣe idajọ mi, ati ti iwọ o si pa gbogbo ofin mi mọ lati ma rin ninu wọn, nigbana ni emi o mu ọ̀rọ mi ṣẹ pẹlu rẹ, ti mo ti sọ fun Dafidi, baba rẹ;

13. Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi.

14. Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀.

15. O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na.

16. O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ.

17. Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn.

18. Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan.

19. Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 6