Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 6:29-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode.

30. Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode.

31. Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri.

32. Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ.

33. Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na.

34. Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po.

35. O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́.

36. O si fi ẹsẹsẹ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ẹsẹ kan ìti kedari kọ́ agbala ti inu ọhun.

37. Li ọdun kẹrin li a fi ipilẹ ile Oluwa le ilẹ̀, li oṣu Sifi.

38. Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 6