Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 6:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa.

2. Ile na ti Solomoni ọba kọ́ fun Oluwa, gigun rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ibú rẹ̀, ogun igbọnwọ, ati giga rẹ̀, ọgbọn igbọnwọ.

3. Ati ọ̀dẹdẹ niwaju tempili ile na, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, gẹgẹ bi ibú ile na: igbọnwọ mẹwa si ni ibú rẹ̀ niwaju ile na.

4. Ati fun ile na ni a ṣe ferese fun síse.

5. Lara ogiri ile na li o bù yàra yika; ati tempili, ati ibi-mimọ́-julọ, li o si ṣe yara yika.

6. Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na.

7. Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.

8. Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta.

9. Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na.

10. O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na.

11. Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe,

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 6