Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 4:4-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa:

5. Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba:

6. Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú.

7. Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese.

8. Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu.

9. Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani:

10. Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi:

11. Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.

12. Baana ọmọ Ahiludi, tirẹ̀ ni Taanaki iṣe, ati Megiddo, ati gbogbo Betṣeani ti mbẹ niha Sartana nisalẹ Jesreeli, lati Betṣeani de Abelmehola, ani titi de ibi ti mbẹ ni ikọja Jokneamu;

13. Ọmọ Geberi ni Ramoti-Gileadi; tirẹ̀ ni awọn ileto Jairi, ọmọ Manasse, ti mbẹ ni Gileadi; tirẹ̀ si ni apa Argobu, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu ti o tobi, ti o li odi ati ọpa-idabu idẹ.

14. Ahinadabu, ọmọ Iddo, li o ni Mahanaimu

15. Ahimaasi wà ni Naftali; on pẹlu li o ni Basmati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 4