Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 4:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SOLOMONI ọba si jẹ ọba lori gbogbo Israeli.

2. Awọn wọnyi ni awọn ijoye ti o ni; Asariah, ọmọ Sadoku alufa,

3. Elihorefu ati Ahiah, awọn ọmọ Ṣiṣa li akọwe, Jehoṣafati ọmọ Ahiludi li akọwe ilu.

4. Ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, li olori-ogun: ati Sadoku ati Abiatari ni awọn alufa:

5. Ati Asariah, ọmọ Natani, li olori awọn ọgagun: Sabudu, ọmọ Natani, alufa, si ni ọrẹ ọba:

6. Ati Ahiṣari li o ṣe olori agbo-ile: ati Adoniramu, ọmọ Abda li o nṣe olori iṣẹ-irú.

7. Solomoni si ni ijoye mejila lori gbogbo Israeli, ti o npèse onjẹ fun ọba ati agbo-ile rẹ̀; olukuluku li oṣu tirẹ̀ li ọdun ni npese.

8. Orukọ wọn si ni wọnyi: Benhuri li oke Efraimu.

9. Bendekari ni Makasi, ati ni Ṣaalbimu ati Betṣemeṣi, ati Elonibethanani:

10. Benhesedi, ni Aruboti; tirẹ̀ ni Soko iṣe ati gbogbo ilẹ Heferi:

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 4