Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 2:43-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ?

44. Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ.

45. A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai.

46. Ọba si paṣẹ fun Benaiah ọmọ Jehoiada, o si jade lọ, o si kọlù u, o si kú. A si fi idi ijọba mulẹ li ọwọ́ Solomoni.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 2