Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 2:23-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Solomoni, ọba si fi Oluwa bura pe, Bayi ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati jubẹ pẹlu, nitori Adonijah sọ̀rọ yi si ẹmi ara rẹ̀.

24. Ati nisisiyi bi Oluwa ti wà, ti o ti fi idi mi mulẹ̀, ti o si mu mi joko lori itẹ́ baba mi, ti o si ti kọ́ ile fun mi, gẹgẹ bi o ti wi, loni ni a o pa Adonijah.

25. Solomoni, ọba si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, o si kọlu u, o si kú.

26. Ati fun Abiatari, alufa, ọba wipe, Lọ si Anatoti, si oko rẹ; nitori iwọ yẹ si ikú: ṣugbọn loni emi kì yio pa ọ, nitori iwọ li o ti ngbe apoti Oluwa Ọlọrun niwaju Dafidi baba mi, ati nitori iwọ ti jẹ ninu gbogbo iyà ti baba mi ti jẹ.

27. Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo.

28. Ihin si de ọdọ Joabu: nitori Joabu ti tọ̀ Adonijah lẹhin, ṣugbọn kò tọ̀ Absalomu lẹhin: Joabu si sá sinu agọ Oluwa, o si di iwo pẹpẹ mu.

29. A si sọ fun Solomoni ọba pe, Joabu ti sá sinu agọ Oluwa; si wò o, o sunmọ pẹpẹ, Solomoni si rán Benaiah, ọmọ Jehoiada, pe, Lọ, ki o si kọlù u.

30. Benaiah si wá sinu agọ Oluwa, o si wi fun u pe, Bayi li ọba wi, pe, Jade wá. On si wipe, Bẹ̃kọ̀; ṣugbọn nihinyi li emi o kú. Benaiah si mu èsi fun ọba wá pe, Bayi ni Joabu wi, bayi ni o si dá mi lohùn.

31. Ọba si wi fun u pe, Ṣe gẹgẹ bi o ti wi ki o si kọlù u, ki o si sin i, ki iwọ ki o le mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lọdọ mi ati kuro lọdọ ile baba mi, ti Joabu ti ta silẹ.

32. Oluwa yio si yi ẹ̀jẹ rẹ̀ pada sori rẹ̀, nitoriti o kọlù ọkunrin meji ti o ṣe olododo, ti o sàn jù on tikararẹ̀ lọ, o si fi idà pa wọn. Dafidi baba mi kò si mọ̀, ani, Abneri, ọmọ Neri, olori ogun, ati Amasa, ọmọ Jeteri, olori ogun Juda.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 2