Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 17:4-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Yio si ṣe, iwọ o mu ninu odò na; mo si ti paṣẹ fun awọn ẹiyẹ iwò lati ma bọ́ ọ nibẹ.

5. O si lọ, o si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa: o si lọ, o si ngbe ẹ̀ba odò Keriti, ti mbẹ niwaju Jordani.

6. Awọn ẹiyẹ iwò si mu akara pẹlu ẹran fun u wá li owurọ, ati akara ati ẹran li alẹ: on si mu ninu odò na.

7. O si ṣe lẹhin ọjọ wọnni, odò na si gbẹ, nitoriti kò si òjo ni ilẹ na.

8. Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá wipe,

9. Dide, lọ si Sarefati ti Sidoni, ki o si ma gbe ibẹ: kiyesi i, emi ti paṣẹ fun obinrin opó kan nibẹ lati ma bọ́ ọ.

10. On si dide, o si lọ si Sarefati. Nigbati o si de ibode ilu na, kiyesi i, obinrin opó kan nṣa igi jọ nibẹ: o si ke si i, o si wipe, Jọ̃, bu omi diẹ fun mi wá ninu ohun-elo, ki emi ki o le mu.

11. Bi o si ti nlọ bù u wá, o ke si i, o si wipe, Jọ̃, mu okele onjẹ diẹ fun mi wá lọwọ rẹ.

12. On si wipe, Bi Oluwa Ọlọrun rẹ ti wà, emi kò ni àkara, ṣugbọn ikunwọ iyẹfun ninu ìkoko, ati ororo diẹ ninu kòlobo: si kiyesi i, emi nṣa igi meji jọ, ki emi ki o le wọle lọ, ki emi ki o si peṣe rẹ̀ fun mi, ati fun ọmọ mi, ki awa le jẹ ẹ, ki a si kú.

13. Elijah si wi fun u pe, Má bẹ̀ru; lọ, ki o si ṣe gẹgẹ bi o ti wi; ṣugbọn ki o tètekọ ṣe àkara kekere kan fun mi ninu rẹ̀ na, ki o si mu u fun mi wá, lẹhin na, ki o ṣe tirẹ ati ti ọmọ rẹ:

14. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: Ikoko iyẹfun na kì yio ṣòfo, bẹni kólobo ororo na kì yio gbẹ, titi di ọjọ ti Oluwa yio rọ̀ òjo si ori ilẹ.

15. O si lọ, o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Elijah: ati on ati obinrin na, ati ile rẹ̀ jẹ li ọjọ pupọ̀.

16. Ikoko iyẹfun na kò ṣòfo, bẹ̃ni kólobo ororo na kò gbẹ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Elijah sọ.

17. O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni ọmọ obinrin na, iya ile na, ṣe aisàn; aisàn rẹ̀ na si le to bẹ̃, ti kò kù ẹmi ninu rẹ̀.

18. On si wi fun Elijah pe, Kili o ṣe mi ṣe ọ, Iwọ enia Ọlọrun? iwọ ha tọ̀ mi wá lati mu ẹ̀ṣẹ mi wá si iranti, ati lati pa mi li ọmọ?

19. On si wi fun u pe, Gbé ọmọ rẹ fun mi. Elijah si yọ ọ jade li aiya rẹ̀, o si gbé e lọ si iyara-òke ile nibiti on ngbe, o si tẹ́ ẹ si ori akete tirẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 17