Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 16:27-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

28. Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

29. Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun,

30. Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ.

31. O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,

32. O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria.

33. Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu.

34. Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 16