Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 16:22-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba.

23. Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa.

24. O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria.

25. Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀.

26. Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.

27. Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

28. Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 16