Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 15:29-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. O si ṣe, nigbati o jọba, o kọlu gbogbo ile Jeroboamu; kò kù fun Jeroboamu ẹniti nmí, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Ọluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah ara Ṣilo:

30. Nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu ti o ṣẹ̀, ti o si mu ki Israeli ṣẹ̀, nipa imunibinu rẹ̀, eyiti o fi mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli ki o binu.

31. Ati iyokù iṣe Nadabu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

32. Ogun si wà, lãrin Asa ati Baaṣa ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.

33. Li ọdun kẹta Asa, ọba Juda, ni Baaṣa, ọmọ Ahijah bẹ̀rẹ si ijọba lori gbogbo Israeli ni Tirsa, li ọdun mẹrinlelogun.

34. O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na Jeroboamu, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 15