Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 15:13-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati Maaka iya rẹ̀ papã, li o si mu kuro lati ma ṣe ayaba, nitori ti o yá ere kan fun oriṣa rẹ̀; Asa si ke ere na kuro; o si daná sun u nibi odò Kidroni.

14. Ṣugbọn ibi giga wọnnì ni a kò mu kuro; sibẹ ọkàn Asa pé pẹlu Oluwa li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.

15. O si mu ohun-mimọ́ wọnnì ti baba rẹ̀, ati ohun-mimọ́ wọnnì ti on tikararẹ̀ wọ ile Oluwa, fadaka ati wura, ati ohun-elo wọnnì,

16. Ogun si wà lãrin Asa ati Baaṣa, ọba Israeli ni gbogbo ọjọ wọn.

17. Baaṣa, ọba Israeli, si goke lọ si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má le jẹ ki ẹnikẹni ki o jade tabi ki o wọle tọ Asa ọba lọ.

18. Nigbana ni Asa mu gbogbo fadaka, ati wura ti o kù ninu iṣura ile Oluwa, ati iṣura ile ọba, o si fi wọn si ọwọ́ awọn iranṣẹ rẹ̀: Asa ọba si rán wọn si ọdọ Benhadadi, ọmọ Tabrimoni, ọmọ Hesioni, ọba Siria, ti o ngbe Damasku, wipe,

19. Jẹ ki majẹmu ki o wà lãrin emi ati iwọ, lãrin baba mi ati baba rẹ, kiye si i, emi ran ọrẹ fadaka ati wura si ọ; wá, ki o si dà majẹmu rẹ pẹlu Baaṣa, ọba Israeli, ki o le lọ kuro lọdọ mi.

20. Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali.

21. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o si ṣiwọ ati kọ́ Rama, o si ngbe Tirsa.

22. Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa.

23. Iyokù gbogbo iṣe Asa, ati gbogbo agbara rẹ̀ ati gbogbo ohun ti o ṣe, ati ilu wọnnì ti o kọ́, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ṣugbọn li akoko ogbó rẹ̀, àrun ṣe e li ẹsẹ rẹ̀.

24. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi baba rẹ̀. Jehoṣafati, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

25. Nadabu ọmọ Jeroboamu si bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli li ọdun keji Asa, ọba Juda, o si jọba lori Israeli li ọdun meji.

26. O si ṣe buburu niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ eyiti o mu Israeli ṣẹ̀.

27. Baaṣa ọmọ Ahijah ti ile Issakari, si dìtẹ si i; Baaṣa kọlu u ni Gibbetoni ti awọn ara Filistia: nitori Nadabu ati gbogbo Israeli dó ti Gibbetoni.

28. Ani li ọdun kẹta ti Asa ọba Juda, ni Baaṣa pa a, o si jọba ni ipò rẹ̀.

29. O si ṣe, nigbati o jọba, o kọlu gbogbo ile Jeroboamu; kò kù fun Jeroboamu ẹniti nmí, titi o fi run u, gẹgẹ bi ọ̀rọ Ọluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah ara Ṣilo:

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 15