Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 14:17-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Aya Jeroboamu si dide, o si lọ, o si de Tira: nigbati o si wọ̀ iloro ile, ọmọde na si kú;

18. Nwọn si sin i; gbogbo Israeli si sọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah woli.

19. Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

20. Awọn ọjọ ti Jeroboamu jọba jẹ ọdun mejilelogun, o si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀. Nadabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

21. Rehoboamu, ọmọ Solomoni, si jọba ni Juda: Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mọkanlelogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.

22. Juda si ṣe buburu niwaju Oluwa, nwọn si fi ẹ̀ṣẹ wọn mu u jowu jù gbogbo eyiti baba wọn ti ṣe, ti nwọn si ti dá.

23. Nitori awọn pẹlu kọ́ ibi giga fun ara wọn, ati ere, ati igbo-oriṣa lori gbogbo oke giga, ati labẹ gbogbo igi tutu.

24. Awọn ti nhùwa panṣaga mbẹ ni ilẹ na: nwọn si ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun irira awọn orilẹ-ède ti Oluwa lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli.

25. O si ṣe li ọdun karun Rehoboamu ọba, Ṣiṣaki, ọba Egipti goke wá si Jerusalemu:

26. O si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; ani gbogbo rẹ̀ li o kó lọ: o si kó gbogbo asà wura ti Solomoni ti ṣe lọ.

27. Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn si ọwọ́ olori awọn oluṣọ ti nṣọ ilẹkun ile ọba.

28. Bẹ̃li o si ri, nigbati ọba ba nlọ si ile Oluwa, nwọn a rù wọn, nwọn a si mu wọn pada sinu yara oluṣọ.

29. Iyokù iṣe Rehoboamu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

30. Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ wọn gbogbo.

31. Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni. Abijah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 14