Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 11:33-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

34. Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́:

35. Ṣugbọn emi o gba ijọba na li ọwọ ọmọ rẹ̀, emi o si fi i fun ọ, ani ẹya mẹwa.

36. Emi o si fi ẹya kan fun ọmọ rẹ̀, ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ.

37. Emi o si mu ọ, iwọ o si jọba gẹgẹ bi gbogbo eyiti ọkàn rẹ nfẹ, iwọ o si jẹ ọba lori Israeli.

38. Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ.

39. Emi o si pọ́n iru-ọmọ Dafidi loju nitori eyi, ṣugbọn kì iṣe titi lai.

40. Nitorina Solomoni wá ọ̀na lati pa Jeroboamu. Jeroboamu si dide, o si sá lọ si Egipti si ọdọ Ṣiṣaki ọba Egipti, o si wà ni Egipti titi ikú Solomoni.

41. Ati iyokù iṣe Solomoni ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe iṣe Solomoni bi?

42. Ọjọ ti Solomoni jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli jẹ ogoji ọdun.

43. Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 11