Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 10:9-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ.

10. On si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọ́pọlọpọ ati okuta iyebiye: iru ọ̀pọlọpọ turari bẹ̃ kò de mọ bi eyiti ayaba Ṣeba fi fun Solomoni, ọba.

11. Pẹlupẹlu awọn ọ̀wọ-ọkọ̀ Hiramu ti o mu wura lati Ofiri wá, mu igi Algumu, (igi Sandali) lọpọlọpọ ati okuta oniyebiye lati Ofiri wá.

12. Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi.

13. Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

14. Njẹ ìwọn wura ti o nde ọdọ Solomoni li ọdun kan, jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura,

15. Laika eyi ti o ngbà lọwọ awọn ajẹlẹ ati awọn oniṣowo, ati ti gbogbo awọn ọba Arabia, ati ti awọn bãlẹ ilẹ.

16. Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: ẹgbẹta ṣekeli wura li o tán si asà kan.

17. O si ṣe ọdunrun apata wura lilù, oṣuwọn wura mẹta li o tán si apata kan: ọba si ko wọn si ile igbo Lebanoni.

18. Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin kan nla, o si fi wura didara julọ bò o.

19. Itẹ́ na ni atẹgùn mẹfa, oke itẹ́ na yi okiribiti lẹhin: irọpá si wà niha kini ati ekeji ni ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba na.

20. Kiniun mejila duro nibẹ niha ekini ati ekeji lori atẹgùn mẹfa na: a kò ṣe iru rẹ̀ ni ijọba kan.

21. Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni jẹ wura daradara; kò si fadaka; a kò kà a si nkankan li ọjọ Solomoni.

22. Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá.

23. Solomoni ọba si pọ̀ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ, li ọrọ̀ ati li ọgbọ́n.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 10