Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 10:24-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Gbogbo aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀, ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.

25. Olukuluku nwọn si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadaka, ati ohun-elo wura, ati ẹ̀wu, ati turari, ẹṣin ati ibãka, iye kan lọdọdun.

26. Solomoni si ko kẹkẹ́ ati èṣin jọ: o si ni egbeje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹsin, o si fi wọn si ilu kẹkẹ́, ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.

27. Ọba si ṣe ki fadakà ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti mbẹ ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.

28. A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti li ọwọ́wọ, oniṣowo ọba nmu wọn wá fun owo.

29. Kẹkẹ́ kan ngoke o si njade lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu wá pẹlu nipa ọwọ wọn fun gbogbo awọn ọba awọn ọmọ Hiti ati fun awọn ọba Siria.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 10