Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 1:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru.

2. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Jẹ ki a wá ọmọbinrin kan, wundia, fun Oluwa mi, ọba: ki o si duro niwaju ọba, ki o si ṣikẹ́ rẹ̀, ki o si dubulẹ li õkan-aiya rẹ̀, oluwa mi, ọba yio si mõru.

3. Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá.

4. Ọmọbinrin na si ṣe arẹwà gidigidi, o si nṣikẹ́ ọba, o si nṣe iranṣẹ fun u; ṣugbọn ọba kò si mọ̀ ọ.

5. Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀.

6. Baba rẹ̀ kò si bà a ninu jẹ rí, pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe bayi? On si ṣe enia ti o dara gidigidi: iya rẹ̀ si bi i le Absalomu.

7. O si ba Joabu, ọmọ Seruiah, ati Abiatari, alufa gbèro: nwọn si nràn Adonijah lọwọ.

8. Ṣugbọn Sadoku alufa, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati Natani woli, ati Ṣimei, ati Rei, ati awọn ọkunrin alagbara ti mbẹ lọdọ Dafidi, kò wà pẹlu Adonijah.

9. Adonijah si pa agutan ati malu ati ẹran ọ̀sin ti o sanra nibi okuta Soheleti, ti mbẹ lẹba Enrogeli, o si pè gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ ọba, ati gbogbo ọkunrin Juda, iranṣẹ ọba:

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 1