Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 8:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. FI ipè si ẹnu rẹ. Yio wá bi idì si ile Oluwa, nitori nwọn ti re majẹmu mi kọja, nwọn si ti rú ofin mi.

2. Nwọn o kigbe si mi pe, Ọlọrun mi, awa Israeli mọ̀ ọ.

3. Israeli ti gbe ohunrere sọnù; ọta yio lepa rẹ̀.

4. Nwọn ti fi ọba jẹ, ṣugbọn kì iṣe nipasẹ̀ mi: nwọn ti jẹ olori, ṣugbọn emi kò si mọ̀: fàdakà wọn ati wurà wọn ni nwọn fi ṣe òriṣa fun ara wọn, ki a ba le ké wọn kuro.

5. Ọmọ-malu rẹ ti ta ọ nù, Samaria; ibinu mi rú si wọn: yio ti pẹ to ki nwọn to de ipò ailẹ̀ṣẹ?

6. Nitori lati ọdọ Israeli wá li o ti ri bẹ̃ pẹlu; oniṣọ̀na li o ṣe e; nitorina on kì iṣe Ọlọrun: ṣugbọn ọmọ malu Samaria yio fọ tũtũ.

7. Nitori nwọn ti gbìn ẹfũfũ, nwọn o si ka ãjà: kò ni igi ọka: irúdi kì yio si mu onjẹ wá: bi o ba ṣepe o mu wá, alejò yio gbe e mì.

8. A gbe Israeli mì: nisisiyi ni nwọn o wà lãrin awọn Keferi bi ohun-elò ninu eyiti inu-didùn kò si.

9. Nitori nwọn goke lọ si Assiria, kẹtẹ́kẹtẹ́ igbẹ́ nikan fun ara rẹ̀: Efraimu ti bẹ̀ awọn ọrẹ li ọ̀wẹ.

10. Nitõtọ, bi nwọn tilẹ ti bẹ̀ ọ̀wẹ lãrin awọn orilẹ-ède, nisisiyi li emi o ko wọn jọ, nwọn o si kãnu diẹ fun ẹrù ọba awọn ọmọ-alade.

Ka pipe ipin Hos 8