Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 7:10-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Igberaga Israeli si njẹri si i li oju rẹ̀; nwọn kò si yipadà si Oluwa Ọlọrun wọn, bẹ̃ni fun gbogbo eyi nwọn kò si wá a.

11. Efraimu pẹlu dabi òpe adàba ti kò li ọkàn; nwọn kọ si Egipti, nwọn lọ si Assiria.

12. Nigbati nwọn o lọ, emi o nà àwọn mi le wọn; emi o mu wọn wá ilẹ bi ẹiyẹ oju-ọrun; emi o nà wọn, bi ijọ-enia wọn ti gbọ́.

13. Egbe ni fun wọn! nitori nwọn ti sá kuro lọdọ mi: iparun ni fun wọn! nitori nwọn ti ṣẹ̀ si mi: bi o tilẹ ṣepe mo ti rà wọn padà, ṣugbọn nwọn ti ṣe eké si mi.

14. Nwọn kò si ti fi tọkàntọkàn ké pè mi, nigbati nwọn hu lori akete wọn: nwọn kó ara wọn jọ fun ọkà ati ọti-waini, nwọn si ṣọ̀tẹ si mi.

15. Bi mo ti dì, ti mo si fun apa wọn li okun, sibẹ̀ nwọn nrò ibi si mi.

16. Nwọn yipadà, ṣugbọn kì iṣe si Ọga-ogo: nwọn dàbi ọrun ẹtàn; awọn ọmọ-alade wọn yio tipa idà ṣubu, nitori irúnu ahọn wọn: eyi ni yio ṣe ẹsín wọn ni ilẹ Egipti.

Ka pipe ipin Hos 7