Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 4:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli; nitori Oluwa ni ẹjọ kan ba awọn ara ilẹ na wi, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na.

2. Nipa ibura, ati eke, ati ipani, ati olè, ati iṣe panṣaga, nwọn gbìjà, ẹ̀jẹ si nkàn ẹ̀jẹ.

3. Nitorina ni ilẹ na yio ṣe ṣọ̀fọ, ati olukuluku ẹniti ngbé inu rẹ̀ yio rọ, pẹlu awọn ẹranko igbẹ, ati pẹlu awọn ẹiyẹ oju ọrun; a o si mu awọn ẹja inu okun kuro pẹlu.

Ka pipe ipin Hos 4